A bá arábìnrin Fatimah Aderohunmu tó ní ìpènijà ‘Muscular Dystrophy’ sọ̀rọ̀ nípa bí àìlera rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.

Ó ṣàlàyé ohun tí àìsàn náà jẹ́ àti bí ó ṣe ti ń bá a yí láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó sì ṣàlàyé bí ó ṣe kọ̀wé nípa rẹ̀ láti fi ró àwọn Onípènijà akẹgbẹ́ rẹ̀ lágbára.